1 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa, Olúwa sì fi wọ́n lé àwọn ará Fílístínì lọ́wọ́ fún ogójì (40) ọdún.
2 Ọkùnrin ará Sórà kan wà, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Mánóà láti ẹ̀yà Dánì. Aya rẹ̀ yàgàn kò sì bímọ.
3 Ańgẹ́lì Olúwa fara han obìnrin náà, ó sì wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yàgàn, ìwọ kò sì tíì bímọ, ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.
4 Báyìí rí i dájúdájú pé ìwọ kò mu wáìnì tàbí ọtí líle kankan àti pé ìwọ kò jẹ ohun aláìmọ́ kankan,
5 nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Má se fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Násírì (ẹni ìyàsọ́tọ̀) Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run láti ọjọ́ ìbí rẹ̀. Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Fílístínì.”
6 Nígbà náà ni obìnrin náà tọ ọkọ rẹ̀ lọ, o sì sọ fún un wí pé, “Èniyàn Ọlọ́run kan tọ̀ mí wá. Ó jọ ańgẹ́lì Ọlọ́run, ó bà ènìyàn lẹ́rù gidigidi. Èmi kò béèrè ibi tí ó ti wá, òun náà kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi.
7 Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi wí pé, ‘Ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, fún ìdí èyí, má ṣe mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ má se jẹ ohunkóhun tí í ṣe aláìmọ́, nítorí pé Násírì Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’ ”
8 Nígbà náà ni Mánóà gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Háà Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tí ìwọ rán sí wa padà tọ̀ wá wá láti kọ́ wa bí àwa yóò ti ṣe tọ́ ọmọ tí àwa yóò bí náà.”
9 Ọlọ́run fetí sí ohùn Mánóà, ańgẹ́lì Ọlọ́run náà tún padà tọ obìnrin náà wá nígbà tí ó wà ní oko: Ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ Mánóà kò sí ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.
10 Nítorí náà ni obìnrin náà ṣe yára lọ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó fara hàn mí ní ọjọ́sí ti tún padà wá.”
11 Mánóà yára dìde, ó sì tẹ̀lé aya rẹ̀, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin náà ó ní, “Ǹjẹ́ ìwọ ni o bá obìnrin yìí sọ̀rọ̀?”Ọkùnrin náà dáhùn pé “Èmi ni.”
12 Mánóà bi ọkùnrin náà pé, “Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ kí ni yóò jẹ́ ìlànà fún ìgbé ayé àti iṣẹ́ ọmọ náà?”
13 Ańgẹ́lì Olúwa náà dáhùn wí pé, “Aya rẹ gbọdọ̀ ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ fún un
14 kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti inú èṣo àjàrà jáde wá, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn tàbí jẹ ohunkóhun tí ó bá jẹ́ aláìmọ́. Ó ní láti ṣe ohun gbogbo tí mo ti pa láṣẹ fún un.”
15 Mánóà sọ fún ańgẹ́lì Olúwa náà pé, “Jọ̀wọ́ dára dúró títí àwa yóò fi pèṣè ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan fún ọ.”
16 Ańgẹ́lì Olúwa náà dá Mánóà lóhùn pé, “Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, Èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹyin yóò pèṣè. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèṣè ọrẹ ẹbọ ṣíṣun, kí ẹ sì fi rúbọ sí Olúwa.” (Mánóà kò mọ̀ pé ańgẹ́lì Olúwa ní i ṣe.)
17 Mánóà sì béèrè lọ́wọ́ ańgẹ́lì Olúwa náà pé, “Kí ni orúkọ rẹ, kí àwa bá à lè fi ọlá fún ọ nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?”
18 Ṣùgbọ́n ańgẹ́lì Olúwa náà dáhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ ń béèrè ọrúkọ mi? Ìyanu ni, ó kọjá ìmọ̀.”
19 Lẹ́yìn náà ni Mánóà mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọkà, ó sì fi rúbọ lórí àpáta kan sí Olúwa. Nígbà tí Mánóà àti ìyàwó dúró tí wọn ń wò Olúwa ṣe ohun ìyanu kan.
20 Bí ẹ̀là ahọ́n iná ti là jáde láti ibi pẹpẹ ìrúbọ náà sí ọ̀run, ańgẹ́lì Olúwa gòkè re ọ̀run láàárin ahọ́n iná náà. Nígbà tí wọ́n rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Mánóà àti aya rẹ̀ wólẹ̀ wọ́n sì dojú bolẹ̀.
21 Nígbà tí ańgẹ́lì Olúwa náà kò tún fi ara rẹ̀ han Mánóà àti aya rẹ̀ mọ́, Mánóà wá mọ̀ pé ańgẹ́lì Olúwa ni.
22 Mánóà sọ fún aya rẹ̀ pé, “Dájúdájú àwa yóò kú nítorí àwa ti fi ojú rí Ọlọ́run.”
23 Ṣùgbọ́n ìyàwó rẹ̀ dáhùn pé, “Bí Olúwa bá ní èrò àti pa wá kò bá tí gba ọrẹ ṣísun àti ọrẹ ọkà wa, tàbí fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá tó sọ nǹkan ìyanu yìí fún wa.”
24 Obínrìn náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ṣáḿsónì. Ọmọ náà dàgbà Olúwa sì bùkún un.
25 Ẹ̀mí Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nígbà tí ó wà ní Máháne-dánì ní agbede-méjì Sórà àti Ésítaólì.