Onídájọ́ 1 BMY

Orílẹ̀-Èdè Ísírẹ́lì Bá Àwọn Ará Kénánì Tó Kù jagun

1 Lẹ́yìn ikú Jóṣúà, ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé “Èwo nínú ẹ̀yà wa ni yóò kọ́kọ́ gòkè lọ bá àwọn ará Kénánì jagun fún wa?”

2 Olúwa sì dáhùn pé, “Júdà ni yóò lọ; nítorí pé èmi ti fi ilẹ̀ náà lé e lọ́wọ́.”

3 Nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Júdà béèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣíméónì arákùrin wọn pé, “Ẹ wá bá wa gòkè lọ sí ilẹ̀ tí a ti fi fún wa, láti bá àwọn ará Kénánì jà kí a sì lé wọn kúrò, àwa pẹ̀lú yóò sì bá a yín lọ sí ilẹ̀ tiyín bákan náà láti ràn yín lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ ogun Síméónì sì bá àwọn ọmọ ogun Júdà lọ.

4 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Júdà sì kọ lu àwọn ọmọ Kénánì, Olúwa ran àwọn Júdà lọ́wọ́, ó sì fi àwọn ará Kénánì àti àwọn ará Párísì lé wọn lọ́wọ́, àwọn Júdà sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ní Béṣékì nínú àwọn ọ̀ta wọn.

5 Ní Béṣékì ni wọ́n ti rí Adoni-Bésékì (Olúwa mi ní Béṣékì), wọ́n sì bá a jagun, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ará Kénánì àti Párísì.

6 Ọba Adoni-Bésékì sá àṣálà, ṣùgbọ́n ogun Ísírẹ́lì lépa rẹ̀ wọ́n sì bá a, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ rẹ̀.

7 Nígbà náà ni ó wí pé, àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń sa ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Báyìí Olúwa ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn, wọ́n sì mú un wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì kú sí bẹ̀.

8 Àwọn ológun Júdà sì ṣẹ́gun Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà.

9 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kénánì tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní Gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀ oòrùn Júdà jagun.

10 Ogun Júdà sì tún sígun tọ ará Kénánì tí ń gbé Hébírónì (tí ọrúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kíríátì-Arábà) ó sì sẹ́gun Ṣẹ́ṣáì-Áhímánì àti Táímà.

11 Lẹ́yìn èyí wọ́n tẹ̀ṣíwájú láti bá àwọn tí ń gbé Débírì jagun (orúkọ Débírì ní ìgbà àtijọ́ ni Kíríátì-Ṣéférì tàbí ìlú àwọn ọ̀mọ̀wé).

12 Kélẹ́bù sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́ ṣíwájú ogun tí Kíríátì-Ṣáférì tí ó sì Ṣẹ́gun rẹ̀ ni èmi ó fún ní ọmọbìnrin mi Ákíṣà gẹ́gẹ́ bí aya.”

13 Ótíníẹ́lì ọmọ Kénásì àbúrò Kélẹ́bù ṣíwájú, wọ́n sì kọ lu ìlú náà, ó sì fún un ní Ákíṣà gẹ́gẹ́ bí aya.

14 Ní ọjọ́ kan nígbà tí Ákíṣà wá sí ọ̀dọ̀ Ótíníélì, ó rọ ọkọ rẹ̀ láti tọrọ oko lọ́wọ́ Kélẹ́bù baba rẹ̀. Nígbà tí Ákíṣà ti sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ Kélẹ́bù bi í léèrè pé, “Kí ni o ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ.”

15 Ákíṣà sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojú rere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní Gúúsù (gúṣù) fún mi ní ìṣun omi náà pẹ̀lú.” Kélẹ́bù sì fún un ní ìṣun òkè àti ìṣun ìṣàlẹ̀.

16 Àwọn ìran Kénì tí wọ́n jẹ́ àna Móṣè bá àwọn Júdà gòkè ní gúṣù nítorí Árádì àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì sì jùmọ̀ ń gbé pọ̀ láti ìgbà náà.

17 Ó sì ṣe, àwọn ológun Júdà tẹ̀lé àwọn ológun Ṣíméónì arákùnrin wọn, wọ́n sì lọ bá àwọn ará Kénánì tí ń gbé Ṣéfátì jagun, wọ́n sì run ìlú náà pátapáta, ní báyìí à ò pe ìlú náà ní Hómà (Hómà èyí tí ń jẹ́ ìparun).

18 Àwọn ogun Júdà sì ṣẹ́gun Gásà àti àwọn agbègbè rẹ̀, Ásíkélénì àti Ékírónì pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó yí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ká.

19 Olúwa sì wà pẹ̀lú ẹ̀yà Júdà, wọ́n gba ilẹ̀ òkè ṣùgbọ́n wọn kò le lé àwọn ènìyàn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí wọ́n ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin.

20 Gẹ́gẹ́ bí Móṣè ti ṣèlérí, wọ́n fún Kélẹ́bù ní Hébírónì ó sì lé àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kúrò; àwọn náà ni ìran àwọn ọmọ Ánákì mẹ́ta.

21 Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni wọn kò le lé àwọn Jébúsì tí wọ́n ń gbé Jérúsálẹ́mù nítorí náà wọ́n ń gbé àárin àwọn Ísírẹ́lì títí di òní.

22 Àwọn ẹ̀yà Jóṣẹ́fù sì bá Bẹ́tẹ́lì jagun, Olúwa ṣíwájú pẹ̀lú wọn.

23 Nígbà tí ẹ̀yà Jóṣẹ́fù rán àwọn ènìyàn láti lọ yọ́ Bẹ́tẹ́lì wò (orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí ni Lúsì).

24 Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ọ̀nà àti wọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mìí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ.”

25 Ó sì fi ọ̀nà ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ si.

26 Ọkùnrin náà sí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hítì, ó sì tẹ ìlú kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lúsì èyí sì ni orúkọ rẹ̀ títí di òní.

27 Àwọn ẹ̀yà Mánásè sì kùnà láti lé àwọn tí ń gbé Bẹti-Sésínì àti àwọn ìlú agbègbè wọn jáde, tàbí àwọn ará Tánákì àti àwọn ìgbéríko rẹ̀, tàbí àwọn olùgbé Mégídò àti àwọn ìgbéríko tí ó yí i ká torí pé àwọn ará Kénánì ti pinnu láti máa gbé ìlú náà.

28 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di alágbára, wọ́n mú àwọn ará Kénánì sìn bí i ẹrú, ṣùgbọ́n wọn kò fi agbára lé wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà.

29 Éfúráímù náà kò lé àwọn ará Kénánì tí ó ń gbé Géṣérì jáde, ṣùgbọ́n àwọn ará Kénánì sì ń gbé láàrin àwọn ẹ̀yà Éfúráímù.

30 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹ̀yà Ṣébúlúnì náà kò lé àwọn ará Kítírónì tàbí àwọn ará Nẹ́hálólì ṣùgbọ́n wọ́n sọ wọ́n di ẹrú. Wọ́n sì ń sin àwọn ará Ṣébúlúnì.

31 Bẹ́ẹ̀ ni Áṣérì kò lé àwọn tí ń gbé ní Ákò àti Áhálábì àti Ákísíbì àti Hélíbáhà àti Háfékì àti Réhóbù.

32 Ṣùgbọ́n nítorí àwọn Áṣérì ń gbé láàrin àwọn ará Kénánì tí wọ́n ni ilẹ̀ náà.

33 Àwọn ẹ̀yà Náfítalì pẹ̀lú kò lé àwọn ará Bétì-Ṣémésì àti Bẹti-Ánátì jáde; ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Náfítanì náà ń gbé àárin àwọn ará Kénánì tí ó ti ní ilẹ̀ náà rí, ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbé Bẹti-Ṣéméṣì àti Bẹti-Ánátì ń sìn ìsìn tipátipá.

34 Àwọn ará Ámórì fi agbára dá àwọn ẹ̀yà Dánì dúró sí àwọn ìlú orí òkè, wọn kò sì jẹ́ kí wọn sọ̀kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀.

35 Àwọn ará Ámórì ti pinnu láti dúró lórí òkè Hérésì àti òkè Áíjálónì àti ti Ṣáíbímù, ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yà Jósẹ́fù di alágbára wọ́n borí Ámórì wọ́n sì mú wọn sìn.

36 Ààlà àwọn ará Ámórì sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgòkè Ákírábímù kọjá lọ sí Ṣélà àti síwájú sí i.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21