Onídájọ́ 11 BMY

1 Jẹ́fítà ará Gílíádì jẹ́ akọni jagunjagun. Gílíádì ni baba rẹ̀; ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ jẹ́ aṣẹ́wó.

2 Ìyàwó Gílíádì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un, nígbà tí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí dàgbà, wọ́n rán Jẹ́fità jáde kúrò nílé, wọ́n wí pé, “Ìwọ kì yóò ní ogún kankan ní ìdílé wa, nítorí pé ìwọ jẹ́ (ọmọ aṣẹ́wó) ọmọ obìnrin mìíràn.”

3 Jẹ́fità sì sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì pàgọ́ sí ilẹ̀ Tóbù, ó sì ń gbé níbẹ̀, níbẹ̀ ni àwọn ènìyàn kan ti ń tẹ ofìn lójú para pọ̀ láti máa tẹ̀lé e kiri.

4 Ní àsìkò kan, nígbà tí àwọn ará Ámónì dìde ogun sí àwọn Ísírẹ́lì,

5 Àwọn ìjòyè: aṣíwájú Gílíádì tọ Jẹ́fítà lọ láti pè é wá láti ilẹ̀ Tóbù.

6 Wọ́n wí fún Jẹ́fità wí pé, “Wá kí o sì jẹ́ olórí ogun wa kí a lè kọjú ogun sí àwọn ará Ámónì.”

7 Jẹ́fítà sì dáhùn pé, “Ṣé kì í ṣe pé ẹ kóríra mi tí ẹ sì lé mi kúrò ní ilé baba mi? Kí ló dé tí ẹ fi tọ̀ mí wá báyìí nígbà tí ẹ wà nínú wàhálà?”

8 Àwọn ìjòyè: àgbà Gílíádì dáhùn pé, “Nítorí rẹ̀ ni àwa fi yípadà sí ọ báyìí: tẹ̀lé wa, kí a lè dojú ìjà kọ àwọn ará Ámónì, ìwọ yóò sì jẹ olórí wa àti gbogbo àwa tí ń gbé ní Gílíádì.”

9 Jẹ́fità dáhùn pé, “Bí ẹ̀yin bá mú mi padà láti bá àwọn ará Ámónì jà àti tí Olúwa bá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́: ṣe èmi yóò jẹ́ olórí yín nítòótọ́.”

10 Àwọn ìjòyè Gílíádì dáhùn pé, “Àwa fi Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí: àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá wí.”

11 Jẹ́fità sì tẹ̀lé àwọn olóyè Gílíádì lọ, àwọn ènìyàn náà sì fi ṣe olórí àti ọ̀gágun wọn. Jẹ́fità sì tún sọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ níwájú Olúwa ní Mísípà.

12 Jẹ́fítà sì rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba àwọn ará Ámónì pé, “Kí ni ẹ̀ṣùn tí o ní sí wa láti fi kàn wá tí ìwọ fi dojú ìjà kọ ilẹ̀ wa?”

13 Ọba àwọn Ámónì dá àwọn oníṣẹ́ Jẹ́fità lóhùn pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ti Éjíbítì wá. Wọ́n gba ilẹ̀ mi láti Ánónì dé Jábókù, àní dé Jọ́dánì, nítorí náà dá wọn padà lọ ní àlàáfíà àti ní pẹ̀lẹ́ kùtù.”

14 Jẹ́fítà sì tún ránṣẹ́ padà sí ọba àwọn ará Ámónì

15 ó sì wí fún un pé:“Báyìí ni Jẹ́fítà wí: àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gba ilẹ̀ Móábù tàbí ilẹ̀ àwọn ará Ámónì.

16 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Éjíbítì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la ihà kọjá lọ sí ọ̀nà òkun pupa wọ́n sì lọ sí Kádésì.

17 Nígbà náà Ísírẹ́lì rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba Édómù pé, ‘Gbà fún wa láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá,’ ṣùgbọ́n ọba Édómù kò fetí sí wọn. Wọ́n tún ránṣẹ́ sí ọba Móábù bákan náà òun náà kọ̀. Nítorí náà Ísírẹ́lì dúró sí Kádésì.

18 “Wọ́n rin ihà kọjá, wọ́n pẹ́ àwọn ilẹ̀ Édómù àti ti Móábù sílẹ̀, nígbà tí wọ́n gba apá ìlà oòrùn Móábù, wọ́n sì tẹ̀dó sí apá kejì Ánónì. Wọn kò wọ ilẹ̀ Móábù, nítorí pé ààlà rẹ̀ ni Ánónì wà.

19 “Nígbà náà ni Ísírẹ́lì rán àwọn oníṣẹ́ sí Síhónì ọba àwọn ará Ámórì, ẹni tí ń ṣe àkóso ní Hésíbónì, wọ́n sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí a la ilẹ̀ rẹ kọja lọ sí ibùgbé wa.’

20 Ṣùgbọ́n Síhónì kò gba Ísírẹ́lì gbọ́ (kò fọkàn tán an) láti jẹ́ kí ó kọjá. Ó kó gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ, ó sì tẹ̀dó sí Jáhásì láti bá Ísírẹ́lì jagun.

21 “Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì fi Síónì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. Ísírẹ́lì sì gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Ámórì tí wọ́n ń gbé ní agbégbé náà,

22 wọ́n gbà gbogbo agbégbé àwọn ará Ámórì tí ó fi dé Jábókù, àti láti aṣálẹ̀ dé Jọ́dánì.

23 “Wàyí o, nígbà tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti lé àwọn ará Ámórì kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀; Ísírẹ́lì, ẹ̀tọ́ wo ni ẹ ní láti gba ilẹ̀ náà?

24 Ǹjẹ́ ìwọ kì yóò ha gba èyí tí Kémọ́sì òrìṣà rẹ fí fún ọ? Bákan náà àwa yóò gba èyíkéyìí tí Olúwa Ọlọ́run wa fi fún wa.

25 Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn jú Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù lọ? Ǹjẹ́ òun ha ṣe gbólóhùn aṣọ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì bí? Tàbí òun dojú ìjà kọ wọ́n rí bí?

26 Fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300) ni Ísírẹ́lì fi ṣe àtìpó ní Hésíbónì, Áróérì àti àwọn ìgbéríko àti àwọn ìlú tí ó yí Ánónì ká. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbà wọ́n padà ní àsìkò náà?

27 Èmi kọ́ ni ó ṣẹ̀ ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ ni ó ṣẹ̀ mí nípa kíkógun tọ̀ mí wá. Jẹ́ kí Olúwa olùdájọ́, ṣe ìdájọ́ lónìí láàárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ará Ámónì.”

28 Ṣùgbọ́n ọba àwọn Ámónì kò fetí sí iṣẹ́ tí Jẹ́fítà rán síi.

29 Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Jẹ́fítà òun sì la Gílíádì àti Mánásè kọjá. Ó la Mísípà àti Gílíádì kọja láti ibẹ̀, ó tẹ̀ṣíwájú láti bá àwọn ará Ámónì jà.

30 Jẹ́fítà sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa pé, “Bí ìwọ bá fi àwọn ará Ámónì lé mi lọ́wọ́,

31 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde láti ẹnu ọ̀nà mi láti wá pàdé mi, nígbà tí èmi bá ń padà bọ̀ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọmọ Ámónì yóò jẹ́ ti Olúwa, èmi yóò sì fi rúbọ bí ọrẹ ẹbọ ṣíṣun.”

32 Jẹ́fítà sì jáde lọ láti bá àwọn ará Ámónì jagun, Olúwa sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́.

33 Òun sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa wọ́n ní àpa tán láti Áróérì títí dé agbègbè Mínítì, ó jẹ́ ogún ìlú, títí dé Abeli-Kérámímù. Báyìí ni Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun àwọn ará Ámónì.

34 Nígbà tí Jẹ́fítà padà sí ilé rẹ̀ ní Mísípà, wò ó, ọmọ rẹ̀ obìnrin ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀ pẹ̀lú taboríìnì àti ijó. Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó ní: kò ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn yàtọ̀ sí òun nìkan.

35 Ní ìgbà tí ó rí i ó fa aṣọ rẹ̀ ya ní ìbànújẹ́, ó sì ké wí pé, “Háà! Ọ̀dọ́mọbìnrin mi, ìwọ fún mi ní ìbànújẹ́ ọkàn ìwọ sì rẹ̀ mí sílẹ̀ gidigidi, nítorí pé èmi ti ya ẹnu mi sí Olúwa ní ẹ̀jẹ́, èmi kò sì le ṣẹ́ ẹ̀jẹ́ mi.”

36 Ọmọ náà sì dáhùn pé, “Baba mi bí ìwọ bá ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, ní báyìí tí Olúwa ti gba ẹ̀ṣan fún ọ lára àwọn ọ̀ta rẹ, àwọn ará Ámónì.

37 Ṣùgbọ́n yọ̀ǹda ìbéèrè kan yìí fún mi, gbà mí láàyè oṣù méjì láti rìn ká orí àwọn òkè, kí n ṣunkún pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi torí mo jẹ́ wúndíá tí n kò sì ní lè ṣe ìgbéyàwó.”

38 Jẹ́fítà dá lóhùn pé, “Ìwọ lè lọ.” Ó sì gbà á láàyè láti lọ fún oṣù méjì. Òun àti àwọn ọmọbìnrin yóòkù lọ sí orí àwọn òkè, wọ́n ṣunkún nítorí pé kì yóò lè ṣe ìgbéyàwó.

39 Lẹ́yìn oṣù méjì náà, ó padà tọ baba rẹ̀ wá òun sì ṣe sí i bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti jẹ́. Ọmọ náà sì jẹ́ wúndíá tí kò mọ ọkùnrin rí.Èyí sì bẹ̀rẹ̀ àṣà kan ní Ísírẹ́lì

40 wí pé ní ọjọ́ mẹ́rin láàrin ọdún àwọn obìnrin Ísírẹ́lì a máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti ṣe ìrántí ọmọbìnrin Jẹ́fítà ti Gílíádì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21