Onídájọ́ 7 BMY

Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Mídíánì

1 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Jérúb-báálì (èyí ni Gídíónì) pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kó ogun jọ lẹ́bá a oríṣun Háṣódì. Àwọn ogun Mídíánì sì wà ní apá àríwá tí wọ́n ní àfonífojì tí ó wà ní ẹ̀bá òkè Mórè.

2 Olúwa wí fún Gídíónì pé, “Àwọn ọmọ ogun tí o kó jọ sọ́dọ̀ ti pọ̀ jù fún mi láti fi àwọn ogun Mídíánì lé wọn lọ́wọ́, kí Ísírẹ́lì má ba à gbé ara rẹ̀ ga sí mi wí pé agbára òun ni ó gbà á là,

3 sì kéde sí àwọn ènìyàn nísinsìn yìí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbọ̀n, tí ó sì ń bẹ̀rù lè padà sẹ́yìn, kí ó sì kúrò lórí òkè Gílíádì.’ ” Báyìí ni Gídíónì ṣe ya àwọn ènìyàn náà. Ẹgbẹ̀rúnméjìlélógún ọkùnrin sì padà sẹ́yìn àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì dúró.

4 Olúwa sì tún sọ fún Gídíónì pé, “Àwọn ènìyàn yìí sì tún pọ̀ jù. Kó wọn lọ sí ibi tí omi wà, èmi yóò sì yọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọ. Bí mo bá wí pé eléyìí yóò bá ọ lọ yóò lọ, ṣùgbọ́n tí mo bá sọ pé, ‘Eléyìí kò ní bá ọ lọ,’ òun kò gbọdọ̀ lọ.”

5 Gídíónì sì kó àwọn ọkùnrin náà lọ sí ibi ìṣun omi. Níbẹ̀ ni Olúwa ti wí fún un pé, “Kí ó pín àwọn ènìyàn náà sí ọ̀nà méjì. Ya àwọn tí ó fi ahọ́n wọn lá omi bí ajá kúrò lára àwọn tí ó kúnlẹ̀ láti mu omi pẹ̀lú ọwọ́ wọn.”

6 Ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin ni ó lá omi pẹ̀lú ahọn wọn. Gbogbo àwọn ìyókù ni ó kúnlẹ̀ láti mu mi.

7 Olúwa wí fún Gídíónì pé, “Àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó lá omi ni èmi yóò lò láti gbà yín là àti láti fi ogun Mídíánì lé yín lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn tókù padà sí ilé wọn.”

8 Báyìí ni Gídíónì ṣe dá àwọn Ísírẹ́lì tí ó kù padà sí àgọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó dá àwọn ọ̀ọ́dúrún ọkùnrin náà dúró. Àwọn wọ̀nyí sì gba gbogbo ohun èlò àti fèrè àwọn tí ó ti padà.Ibùdó ogun àwọn Mídíánì wà ní àfonífojì ní ìṣàlẹ̀. Ibi tí ó wà.

9 Ní òru ọjọ́ náà Olúwa sọ fún Gídíónì pé, “Dìde, dojú ogun kọ ibùdó ogun àwọn ará Mídíánì nítorí èmi yóò fi lé ọ lọ́wọ́.

10 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀rù àti kọlù wọ́n bá ń bà ọ́, yọ́ wọ ibùdó wọn lọ kí o mú Púrà ìránṣẹ́ rẹ lọ́wọ́

11 kí o sì fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú ibùdó náà. Lẹ́yìn èyí ọkàn rẹ̀ yóò le láti kọlù ibùdó náà.” Báyìí ni òun àti Púrà ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ ẹnu ọ̀nà ibùdó yìí.

12 Àwọn ará Mídíánì, àwọn ará Ámẹ́lẹ́kì àti gbogbo ènìyàn ìlà oòrùn tó lọ ní àfonífojì bí esú ni wọ́n rí nítorí púpọ̀ wọn. Àwọn ràkúnmí wọn kò sì lóǹkà, wọ́n sì pọ̀ bí yanrìn inú òkun.

13 Gídíónì dé sí àsìkò tí ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ àlá tí ó lá sí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní, “Mo lá àlá kan, nínú àlá náà mo rí àkàrà kan tó ṣe róbótó tí a fi Báálì ṣe ń yí wọ inú ibùdó àwọn ará Mídíánì, ó sì kọlu àgọ́ pẹ̀lú agbára ńlá débi wí pé àgọ́ náà dojú dé, ó sì ṣubú.”

14 Ọ̀rẹ́ rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Èyí kò le túmọ̀ sí ohun mìíràn ju idà Gídíónì ọmọ Jóásì ará Ísírẹ́lì lọ: Ọlọ́run ti fi àwọn ará Mídíánì àti gbogbo ogun ibùdó lé e lọ́wọ́.”

15 Nígbà tí Gídíónì gbọ́ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ sin Ọlọ́run: lẹ́yìn náà ni ó padà sí ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì pè wọ́n pé, “Ẹ dìde! Nítorí pé Ọlọ́run yóò lò yín láti ṣẹ́gun gbogbo ogun Mídíánì.”

16 Nígbà tí ó ti pín àwọn ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì sí ọ̀nà mẹ́ta, ó fi fèrè, pẹ̀lú àwọn òfìfo ìkòkò lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́, iná sì wà nínú àwọn ìkòkò náà.

17 Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí mo bá ṣe. Nígbà tí mo bá dé igun ibùdó wọn ẹ ṣe ohun tí mo bá ṣe.

18 Nígbà tí èmi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi bá fun fèrè wa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà ni gbogbo igun ibùdó tí ẹ̀ bá wà kí ẹ fun àwọn fèrè yín kí ẹ sì hó pé, ‘Fún Ọlọ́run àti fún Gídíónì.’ ”

19 Gídíónì àti àwọn ọgọ́rùn-ún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé òpin ibùdó àwọn ará Mídíánì ní nǹkan bí agogo méjìlá padà. Wọ́n fun fèrè wọn, wọ́n sì tún fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà ní ọwọ́ mọ́lẹ̀.

20 Àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fun fèrè wọn, wọ́n tún fọ́ àwọn ìkòkò wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n mú àwọn àtùpà iná wọn ní ọwọ́ òsì wọn àti fèrè tí wọ́n ń fun ní ọwọ́ ọ̀tún wọn. Wọ́n pariwo hè è pé, “Idà kan fún Olúwa àti fún Gídíónì!”

21 Nígbà tí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan dúró ní ipò rẹ̀ yí ibùdó àwọn Mídíánì ká, gbogbo àwọn ọmọ ogun Mídíánì ń sá káàkiri, wọ́n ń pariwo bí wọ́n ṣe ń sálọ.

22 Nígbà tí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì fun fèrè wọn, Olúwa da ojú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan kọ ẹnìkejì rẹ̀ àti sí gbogbo ojú ọwọ́ wọn. Àwọn ọmọ ogun sì sá títí dé Bẹti Sítà ní ọ̀nà Ṣérérà títí lọ dé ìpínlẹ̀ Abeli-Méhólà ní ẹ̀bá Tábátì.

23 Gbogbo àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì láti ẹ̀yà Náfítalì, Ásérì àti gbogbo Mànásè ni Gídíónì ránṣẹ́ sí, wọ́n wá wọ́n sì lé àwọn ará Mídíánì.

24 Gídíónì tún ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè Éfúráímù wí pé, “Ẹ jáde wá bá àwọn ará Mídíánì jà, kí ẹ tètè gba àwọn omi Jọ́dánì títí dé Bẹti Bárà kí wọ́n tó dé bẹ̀.”Báyìí ni a ṣe pe gbogbo ọkùnrin ológun Éfúráímù jáde tí wọ́n sì gba gbogbo àwọn àbáwọdò Jọ́dánì títí dé Bẹti Bárà.

25 Wọ́n mú méjì nínú àwọn olórí àwọn ará Mídíánì, àwọn náà ni Órébù àti Ṣéébù. Wọ́n pa Órébù nínú àpáta Órébù, wọ́n sì pa Ṣéébù níbi tí àwọn ènìyàn ti mọ̀ fún wáìnì tí a ń pè ní ìfúntí Ṣéébù. Wọ́n lé àwọn ará Mídíánì, nígbà tí wọ́n gbé orí Órébù àti Ṣéébù tọ Gídíónì wá ẹni tí ó wà ní ìhà kejì Jọ́dánì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21