Onídájọ́ 6 BMY

Gídíónì:

1 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa, Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Mídíánì lọ́wọ́ fún ọdún méje.

2 Agbára àwọn ará Mídíánì sì pọ̀ púpọ̀ lórí àwọn Ísírẹ́lì, wọ́n sì hùwà ipá sí wọn, nítorí ìdí èyí, àwọn Ísírẹ́lì sá lọ sí àwọn orí òkè, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn nínú ihò àpáta, àti nínú ọ̀gbun àti ní ibi agbára nínú àpáta.

3 Ní ìgbàkúgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ti gbin ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Mídíánì, àwọn ará Ámélékì àti àwọn ará ìlà oòrùn mìíràn yóò wá láti bá wọn jà.

4 Wọn yóò tẹ̀dó sí orí ilẹ̀ náà, wọn a sì bá irúgbìn wọ̀nyí jẹ́ títí dé Gásà, wọn kì í sì í fi ohun alààyè kankan ṣílẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kìbáà ṣe àgùntàn, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

5 Wọn a máa wá pẹ̀lú ohun ọ̀sìn wọn àti àwọn àgọ́ wọn, wọn a sì dàbí eṣú nítorí i púpọ̀ wọn. Ènìyàn kò sì lè ka iye àwọn ènìyàn náà bí ni àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n pọ̀ débi pé wọn kò ṣe é kà ní iye, wọn a bo ilẹ̀ náà wọn a sì jẹ ẹ́ run.

6 Àwọn ará Mídíánì sì pọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú, wọ́n sọ wọ́n di òtòsì àti aláìní, fún ìdí èyí wọ́n ké pe Olúwa nínú àdúrà fún ìrànlọ́wọ́.

7 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Olúwa nítorí àwọn ará Mídíánì.

8 Olúwa fi etí sí igbe wọn, ó sì rán wòlíì kan sí wọn. Ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: mo mú yín gòkè ti Éjíbítì wá, láti oko ẹrú.

9 Mo gbà yín kúrò nínú agbára Éjíbítì àti kúrò ní ọwọ́ gbogbo àwọn aninilára yín. Mo lé wọn kúrò ní iwájú yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fún yín.

10 Mo wí fún un yín pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín: ẹ má ṣe sin àwọn òrìṣà àwọn ará Ámórì, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́ràn sí ohun tí mo sọ.”

11 Ní ọjọ́ kan ańgẹ́lì Olúwa wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù ófírà èyí ti ṣe ti Jóásìu ará Ábíésérì, níbi tí Gídíónì ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọn ọtí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Mídíánì.

12 Nígbà tí ańgẹ́lì Olúwa fara han Gídíónì, ó wí fún un pé, “Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, akọni ológun.”

13 Gídíónì dáhùn pé, Alàgbà, bí Olúwa bá wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo ìwọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbi gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ tí àwọn baba wa ròyìn rẹ̀ fún wa nígbà tí wọ́n wí pé, “Olúwa kò ha mú wa gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì wá? Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Mídíánì lọ́wọ́.”

14 Olúwa sì yípadà sí i, ó sì wí fún un pé, “Lọ nínú agbára tí o ní yìí, kí o sì gba àwọn ará Ísírẹ́lì sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì. Èmi ni ó ń rán ọ lọ.”

15 Gídíónì sì dáhùn pé, “Alàgbà Báwo ni èmi ó ṣe gba Ísírẹ́lì là? Ìdílé mi ni ó jẹ́ aláìlera jù ní Mànásè, àti pé èmi ni ó sì kéré jù ní ìdílé bàbá mi.”

16 Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì pa gbogbo àwọn ará Mídíánì láì ku ẹnìkankan.”

17 Gídíónì sì dáhùn pé, nísinsìn yìí tí mo bá bá ojúrere rẹ pàdé, fún mi ní àmì pé ìwọ ni ń bá mi sọ̀rọ̀.

18 Jọ̀wọ́ má ṣe kúrò níbí títí èmi yóò fi mú ọrẹ wá fún ọ kí n sì gbé e sí iwájú rẹ. Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò dúró títí ìwọ yóò fi dé.”

19 Gídíónì sì yára wọ ilé lọ, ó sì pa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan, wọ́n sì ṣè é, ó sì mú ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun éfà kan (èyí tó lítà méjìlélógún) ó fi ṣe àkàrà (àkàrà) àìwú. Ó gbé ẹran náà sínú agbọ̀n ṣùgbọ́n ó fi ọbẹ̀ rẹ̀ sínú ìkòkò, ó gbé wọn jáde tọ ańgẹ́lì náà wá bí ọrẹ lábẹ́ igi óákù.

20 Ańgẹ́lì Olúwa náà sì wí fún un pé, “Gbé ẹran náà àti àkàrà àìwú náà, sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sí orí rẹ̀.” Gídíónì sì ṣe bẹ́ẹ̀.

21 Ańgẹ́lì Olúwa sì fi orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ kan ẹran àti àkàrà àìwú náà. Iná sì jáde láti inú àpáta, ó sì jó ẹran àti àkàrà náà, kò sì rí ańgẹ́lì náà mọ́.

22 Nígbà tí Gídíónì sì ti mọ̀ dájúdájú pé ańgẹ́lì Olúwa ni, ó ké wí pé, “Háà! Olúwa Ọlọ́run alágbára! Mo ti rí ańgẹ́lì Olúwa ní ojú korojú!”

23 Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Àlàáfíà! Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ kì yóò kú.”

24 Báyìí ni Gídíónì mọ pẹpẹ kan fún Olúwa níbẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “Àlàáfíà ni Olúwa.” Ó sì wà ní Ófírà ti Ábíésérì títí di òní.

25 Ní òru ọjọ́ náà Olúwa wí fún un pé, mú akọ màlúù bàbá rẹ kejì láti inú agbo, akọ màlúù ọlọ́dún méje. Wó pẹpẹ Báálì baba rẹ lulẹ̀, kí o sì fọ́ ọ̀pá Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

26 Lẹ́yìn èyí kí o wá mọ pẹpẹ èyí tí ó yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ lórí òkè yìí. Kí o lọ́ igi Áṣírà tí o ké lulẹ̀, kí o fi akọ màlúù kejì rú ẹbọ sísun sí Olúwa.

27 Gídíónì mú mẹ́wàá nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún un ṣùgbọ́n, nítorí ó bẹ̀rù àwọn ará ilé bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ìlú náà kò ṣe é ní ọ̀sán, òru ni ó ṣe.

28 Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, tí àwọn ènìyàn ìlú náà jí, wọ́n rí i pé àti fọ́ pẹpẹ Báálì àti pé a ti bẹ́ igi òpó Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, a sì ti fi akọ màlúù kejì rúbọ lóríi pẹpẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ.

29 Àwọn ènìyàn ìlú náà bi ara wọn wí pé, “Ta ni ó ṣe èyí?”Lẹ́yìn tí wọn fara balẹ̀ ṣe ìwádìí, wọ́n gbọ́ wí pé, “Gídíónì ọmọ Jóásì ni ó ṣe é.”

30 Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún Jóásì wí pé, “Mú ọmọ rẹ jáde wá. Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Báálì lulẹ̀ ó sì ti ké òpó Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.”

31 Ṣùgbọ́n Jóásì bi àwọn èrò tí wọ́n fi ìbínú dúró tì í wí pé, “Ẹ̀yin yóò ha gbìjà Báálì bí? Ẹ̀yin yóò ha gbà á sílẹ̀ bí? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìjà rẹ̀ kíkú ni yóò kú ní òwúrọ̀. Bí Báálì bá ṣe Ọlọ́run ní tòótọ́ yóò jà fún ara rẹ̀ bí ẹnikẹ́ni bá wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.”

32 Fún ìdí èyí ní ọjọ́ náà wọ́n pe Gídíónì ní “Jérúbáálì” wí pé, “Jẹ́kí Báálì bá a jà,” nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Báálì.

33 Láìpẹ́ jọjọ àwọn ogun àwọn Mídíánì, ti àwọn Ámálékì àti ti àwọn ènìyàn ìhà ìlà oòrùn yóòkù kó ara wọn jọ pọ̀ ní ìṣọ̀kan, wọ́n sì kọjá Jọ́dánì wọ́n sì tẹ̀dó sí àfonífojì Jésírẹ́lì.

34 Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Gídíónì, ó sì fun fèrè ìpè, láti pe àwọn ará Ábíésérì láti tẹ̀lé òun.

35 Ó rán àwọn oníṣẹ́ la ilẹ̀ Mánásè já pé kí wọ́n dira ogun, àti sí Ásérì, Ṣébúlúnì àti Náfítalì gbogbo pẹ̀lú sì lọ láti pàdé wọn.

36 Gídíónì wí fún Ọlọ́run pé, “Bí ìwọ yóò bá gba Ísírẹ́lì là nípaṣẹ̀ mi bí ìwọ ti ṣe ìlérí—

37 kíyèsí, èmi yóò fi awọ irun àgùntàn lé ilẹ̀ ìpakà ní alẹ́ òní. Bí ìrì bá ṣẹ̀ sí orí awọ yìí nìkan tí gbogbo ilẹ̀ yóòkù sì gbẹ, nígbà náà ni èmi yóò mọ̀ lóòótọ́ pé ìwọ yóò gba Ísírẹ́lì là nípaṣẹ̀ mi bí ìwọ ti sọ.”

38 Èyí ni ó sì ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Gídíónì jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì ó sì fún irun àgùntàn náà, páànù omi kan sì kún.

39 Gídíónì sì tún wí fún Olúwa pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú sí mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí n tún wá ìdánilójú kan sí i, èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí n fi awọ irun yìí ṣe ìdánwò kan síi. Ní àsìkò yìí, jẹ́ kí awọ irun yìí gbẹ kí gbogbo ilẹ̀ sì tutù pẹ̀lú ìrì.”

40 Ní òru náà Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀, awọ irun àgùntàn nìkan ni ó gbẹ; gbogbo ilẹ̀ yóòkù sì tutù nítorí ìrì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21