Onídájọ́ 21 BMY

Àwọn Aya Fún Àwọn Ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì

1 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti búra ní Mísípà pé: “Kò sí ẹnìkan nínú wa tí yóò fi ọmọ obìnrin rẹ̀ fún ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ní ìyàwó.”

2 Àwọn ènìyàn náà lọ sí Bẹ́tẹ́lì: ilé Ọlọ́run, níbi tí wọ́n jókòó níwájú Ọlọ́run títí di àṣálẹ́, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún kíkorò.

3 Wọ́n sunkún wí pé, “Háà! Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, èéṣe tí nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì? Èéṣe tí ẹ̀yà kan yóò fi run nínú Ísírẹ́lì lónìí?”

4 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì àwọn ènìyàn náà mọ pẹpẹ kan wọ́n sì rúbọ ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ìrẹ́pọ̀ (ìbáṣepọ̀, àlàáfíà).

5 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì béèrè wí pé, “Èwo nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni ó kọ̀ láti péjọ ṣíwájú Olúwa?” Torí pé wọ́n ti fi ìbúra ńlá búra pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti péjọ níwájú Olúwa ní Mísípà pípa ni àwọn yóò pa á.

6 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì banújẹ́ fún àwọn arákùnrin wọn, àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì. Wọ́n wí pé, “A ti ké ẹ̀yà kan kúrò lára Ísírẹ́lì lónìí.”

7 Báwo ni a ó ò ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù, nítorí àwa ti fi Olúwa búra láti má fi ọ̀kankan nínú àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya.

8 Wọ́n sì béèrè wí pé, “È wo ni nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni ó kọ̀ láti bá àwọn ènìyàn péjọ níwájú Olúwa ní Mísípà?” Wọ́n ríì pé kò sí ẹnìkankan tí ó wa láti Jabesi-Gílíádì tí ó wá sí ibùdó fún àjọ náà.

9 Nítorí pé nígbà tí wọ́n ka àwọn ènìyàn, wọ́n rí i pé kò sí ẹnìkan kan láti inú àwọn ará Jabesi-Gílíádì tí ó wà níbẹ̀.

10 Àwọn ìjọ ènìyàn náà sì rán ẹgbàá mẹ́fà àwọn jagunjagun ọkùnrin, lọ sí Jabesi Gílíádì wọ́n fún wọn ní àṣẹ pé, ẹ lọ fi idà kọlu gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.

11 Wọ́n ní, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe, ẹ pa gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tí kì í ṣe wúndíá.”

12 Wọ́n rí àwọn irinwó (400) ọ̀dọ́bìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí nínú àwọn olùgbé Jabesi-Gílíádì, wọ́n sì mú wọn lọ sí ibùdó ní Ṣílò àwọn ará Kénánì.

13 Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ránṣẹ́ àlàáfíà sí àwọn Bẹ́ńjámínì ní ihò àpáta Rímónì.

14 Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì náà sì padà ní àkókò náà, wọ́n sì fún wọn ní àwọn obìnrin Jabesi Gílíádì. Ṣùgbọ́n wọn kò kárí gbogbo wọn.

15 Àwọn ènìyàn náà sì káàánú nítorí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, nítorí Olúwa fi àlàfo kan sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

16 Àwọn olórí ìjọ àwọn ènìyàn náà wí pé, “Kí ni àwa yóò ṣe láti rí aya fún àwọn ọkùnrin tí ó kù nígbà tí a ti pa gbogbo àwọn obìnrin Bẹ́ńjámínì run?”

17 Wọ́n sì wí pé, “Àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n là nínú àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ní láti ní ogún àti àrólé, kí ẹ̀yà kan nínú Ísírẹ́lì má ṣe di píparun kúrò ní orí ilẹ̀.

18 Àwa kò le fi àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya, nítorí tí àwa ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣe ìbúra yìí pé: ‘Ègún ni fún ẹnikẹ́ni tí ó fi aya fún ẹnikẹ́ni nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.’ ”

19 Wọ́n sì wí pé, “Kíyèsí i ayẹyẹ ọlọ́dọọdún fún Olúwa wà ní Ṣílò ní ìhà àríwá Bẹ́tẹ́lì àti ìhà ìlà oòrùn òpópó náà tí ó gba Bẹ́tẹ́lì kọjá sí Ṣékémù, àti sí ìhà gúṣù Lébónà.”

20 Wọ́n sì fi àṣẹ fún àwọn ará Bẹ́ńjámínì pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fara pamọ́ nínú àwọn ọgbà àjàrà

21 kí ẹ sì wà ní ìmúrasílẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin Ṣílò bá jáde láti lọ dara pọ̀ fún ijó, kí ẹ yára jáde láti inú àwọn ọgbà àjàrà wọ̀n-ọn-nì kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbé aya kan nínú àwọn ọmọbìnrin Ṣílò kí ẹ padà sí ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì.

22 Nígbà tí àwọn baba wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn bá fi ẹjọ́ sùn wá, àwa yóò wí fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe wá lóore nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́, nítorí àwa kò rí aya fún wọn ní àkókò ogun, ẹ̀yin kò sì ní jẹ̀bi, nítorí pé ẹ̀yin kọ́ ni ó fi àwọn ọmọbìnrin yín fún wọn bí aya.’ ”

23 Èyí sì ni ohun tí àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣe. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin náà ń jó lọ́wọ́, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan mú ọmọbìnrin kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì gbé e lọ láti di aya rẹ̀. Wọ́n sì padà sí ilẹ̀ ìní wọn, wọ́n sì tún àwọn ìlú náà kọ́, wọ́n sì tẹ̀dó sínú wọn.

24 Ní àkókò náa, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ibẹ̀, wọ́n lọ sí ilé àti ẹ̀yà rẹ̀ olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

25 Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, kò sí ọba ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì; olúkúlùkù sì ń ṣe bí ó ti tọ́ ní ojú ara rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21