3 Jáírì ti ẹ̀yà Gílíádì ni ó dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó ṣàkóso Ísirẹ́lì ní ọdún méjìlélógún.
4 Àwọn ọgbọ̀n ọmọ tí ó ní gún ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n ṣe àkóso ọgbọ̀n ìlú ní Gílíádì, tí a pe orúkọ wọn ní Háfótì Jáírì títí di òní.
5 Nígbà tí Jáírì kú wọ́n sin ín sí Kámónì.
6 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún ṣe ohun tí ó burú lójú Olúwa. Wọ́n sin Báálì àti Áṣítórétù àti àwọn òrìṣà Árámù, òrìṣà Ṣídónì, òrìṣà Móábù, òrìṣà àwọn ará Ámónì àti òrìṣà àwọn ará Fílístínì. Nítorí àwọn ará Ísírẹ́lì kọ Olúwa sílẹ̀ tí wọn kò sì sìn-ín mọ́,
7 ó bínú sí wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ará Fílístínì àti Ámónì láti jẹ ẹ́ ní ìyà.
8 Ní ọdún náà, wọ́n tú wọn ká wọ́n sì pọ́n wọn lójú. Fún ọdún méjìdínlógún ni wọ́n fi ni gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́li tí ó wà ní ìlà oòrùn odò Jọ́dánì ní ilẹ̀ àwọn ará Ámórì lára (èyí nì ní Gílíádì).
9 Àwọn ará Ámónì sì la odò Jọ́dánì kọjá láti bá Júdà, Bẹ́ńjámínì àti àwọn ará ilé Éfúráímù jagun: Ísírẹ́lì sì dojú kọ ìpọ́njú tó lágbára.