27 Èmi kọ́ ni ó ṣẹ̀ ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ ni ó ṣẹ̀ mí nípa kíkógun tọ̀ mí wá. Jẹ́ kí Olúwa olùdájọ́, ṣe ìdájọ́ lónìí láàárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ará Ámónì.”
28 Ṣùgbọ́n ọba àwọn Ámónì kò fetí sí iṣẹ́ tí Jẹ́fítà rán síi.
29 Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Jẹ́fítà òun sì la Gílíádì àti Mánásè kọjá. Ó la Mísípà àti Gílíádì kọja láti ibẹ̀, ó tẹ̀ṣíwájú láti bá àwọn ará Ámónì jà.
30 Jẹ́fítà sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa pé, “Bí ìwọ bá fi àwọn ará Ámónì lé mi lọ́wọ́,
31 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde láti ẹnu ọ̀nà mi láti wá pàdé mi, nígbà tí èmi bá ń padà bọ̀ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọmọ Ámónì yóò jẹ́ ti Olúwa, èmi yóò sì fi rúbọ bí ọrẹ ẹbọ ṣíṣun.”
32 Jẹ́fítà sì jáde lọ láti bá àwọn ará Ámónì jagun, Olúwa sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́.
33 Òun sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa wọ́n ní àpa tán láti Áróérì títí dé agbègbè Mínítì, ó jẹ́ ogún ìlú, títí dé Abeli-Kérámímù. Báyìí ni Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun àwọn ará Ámónì.