Onídájọ́ 14:15-20 BMY

15 Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n wí fún ìyàwó Sámúsónì, pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó lè ṣe àlàyé àlọ́ náà fún wa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò sun ìwọ àti ìdílé baba rẹ̀ ní iná. Tàbí ṣe o pè wá sí ibi àsè yìí láti sọ wá di òtòsì tàbí kó wa lẹ́rú ni?”

16 Nígbà náà ni ìyàwó Sámúsónì ṣubú lé e láyà, ó sì sunkún ní iwájú rẹ̀ pé, “O kórìíra mi! o kò sì ní ìfẹ́ mi nítòótọ́, o pàlọ́ fún àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi.”“Èmi kò tí ì ṣe àlàyé rẹ̀ fún baba àti ìyá mi, báwo ni èmi ó ṣe sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.”

17 Fún gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àsè náà ni ó fi sunkún, nítorí náà ní ọjọ́ keje ó sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún un nítorí pé ó yọ ọ́ lẹ́nu ní ojoojúmọ́. Òun náà sì sọ ìtúmọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ènìyàn rẹ̀

18 Kí ó tó di àṣálẹ́ ọjọ́ keje àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé,“Kí ni ó dùn ju oyin lọ?Kí ni ó sì lágbára ju kìnìún lọ?”Sámúsónì dá wọn lóhùn pé,“Bí kì í bá ṣe pé ẹ fi ọ̀dọ́ màlúù mi kọ ilẹ̀,ẹ̀yin kò bá tí mọ ìtumọ̀ sí àlọ́ mi.”

19 Lẹ́yìn èyí, ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Ó lọ sí Ásíkélónì, ó pa ọgbọ̀n (30) nínú àwọn ọkùnrin wọn, ó gba àwọn ohun ìní wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wọn fún àwọn tí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà. Ó sì padà sí ilé baba rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú ríru.

20 Wọ́n sì fi ìyàwó Sámúsónì fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ rẹ̀ nígbà ìgbéyàwó rẹ̀.