3 Sámúsónì dáhùn pé, “Ní àkókò yìí tí mo bá ṣe àwọn Fílístínì ní ibi èmi yóò jẹ́ aláìjẹ̀bi.”
4 Òun sì jáde lọ, ó mú ọ̀ọ́dúnrún (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ó so ìrù wọn mọ́ ara wọn ní méjìméjì. Ó mú ètùfù iná, ó so ó mọ́ àwọn ìrù tí ó so pọ̀.
5 Ó fi iná ran àwọn ètúfù tí ó so náà, ó sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ sínú àwọn oko ọkà àwọn Fílístínì. Ó jó àwọn pòpóòrò ọkà tí ó dúró àti àwọn tí a dì ní ìtí, ìtí, pẹ̀lú àwọn oko àjàrà àti ólífì.
6 Nígbà tí àwọn Fílístínì béèrè pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Sámúsónì ará Tímínà ni, nítorí o gba ìyàwó rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.”Nítorí náà àwọn Fílístínì lọ wọ́n sì ṣun obìnrin náà àti baba rẹ̀.
7 Sámúsónì sọ fún un pé, “Nítorí pé ẹ̀yin ṣe èyí, èmi kò dẹṣẹ̀ (dúró) títí èmi yóò fi gbẹ̀ṣan mi lára yín.”
8 Ó kọ lù wọ́n pẹ̀lú ìbínú àti agbára ńlá, ó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn. Lẹ́yìn náà ni ó lọ, ó sì dúró nínú ihò àpáta kan nínú àpáta Étamù.
9 Àwọn ará Fílístínì sì dìde ogun sí Júdà, wọ́n ti tan ara wọn ká sí agbégbé Léhì.