Onídájọ́ 20:13-19 BMY

13 Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti Gíbíà yìí wá fún wa, kí àwa lé pa kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní Ísírẹ́lì.”Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ Ísírẹ́lì.

14 Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú wọn sí Gíbíà láti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà.

15 Ní ẹṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ àwọn ará Bẹ́ńjámínì kó ẹgbàá mẹ́talá (26,000) àwọn ọmọ ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé Gíbíà.

16 Ní àárin àwọn ọmọ ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára débi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàṣé (wọ́n jẹ́ ata má tàṣe).

17 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì, yàtọ̀ sí àwọn ará Bẹ́ńjámínì, ka ogún ọ̀kẹ́ àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà.

18 Àwọn ọmọ Ísirẹ́lì lọ sí Bẹ́tẹ́lì (ilé Ọlọ́run) wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n wí pé, “Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará Bẹ́ńjámínì láti bá wọn jà?” Olúwa dáhùn pé, “Júdà ni yóò kọ́ lọ.”

19 Àwọn ọmọ Ísirẹ́lì dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dóti Gíbíà (wọ́n tẹ̀gùn sí ẹ̀bá Gíbíà).