18 Lẹ́yìn tí ó ti fi ẹ̀bùn náà fún ọba tan, ó rán àwọn tí ó kó ẹrú náà wá lọ sí ọ̀nà wọn.
19 Ṣùgbọ́n ní ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí wọ́n ti gbẹ́ òkúta, òun padà ṣẹ́yìn, ó sì wí fún ọba pé, “Mo ní ọ̀rọ̀ àsírí láti bá ọ sọ.”Ọba sì wí pé “Ẹ dákẹ́!” Gbogbo àwọn tí ń sọ sì jáde síta kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
20 Éhúdù lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti jókòó ní iyàrá ìtura rẹ̀, Éhúdù sì wí fún-un pé: “Mo ní ọ̀rọ̀ kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Bí ọba sì ti dìde ní orí ìtẹ́ rẹ̀,
21 Éhúdù fi ọwọ́ òsì rẹ̀ yọ idà láti ibi itan ọ̀tún rẹ̀ ó sì fi gún ọba nínú ikùn rẹ̀.
22 Àti idà àti èèkù rẹ̀ sì wọlé ó sì yọ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Éhúdù kò yọ idà náà, ọ̀rá sì bo idà náà.
23 Éhúdù ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ.
24 Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ilẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, “Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé.”