21 Éhúdù fi ọwọ́ òsì rẹ̀ yọ idà láti ibi itan ọ̀tún rẹ̀ ó sì fi gún ọba nínú ikùn rẹ̀.
22 Àti idà àti èèkù rẹ̀ sì wọlé ó sì yọ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Éhúdù kò yọ idà náà, ọ̀rá sì bo idà náà.
23 Éhúdù ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ.
24 Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ilẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, “Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé.”
25 Nígbà tí wọ́n dúró dé ibi pé ó jẹ́ ìyànu fún wọn, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì sí ilẹ̀kùn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí Olúwa wọn tí ó ti ṣubú, ó sì ti kú.
26 Nígbà tí wọ́n dúró tí wọn sì ń retí, Éhúdù ti sálọ. Ó ti gba ibi tí wọ́n ti ń gbẹ́ òkúta lére, ó sì sálọ sí Ṣéírà.
27 Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó fọn fèrè ní orí òkè Éfúráímù, fèrè ìpè ogun, ó sì kó ogun jọ lábẹ́ ara rẹ̀ bí olórí ogun.