23 Éhúdù ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ.
24 Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ilẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, “Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé.”
25 Nígbà tí wọ́n dúró dé ibi pé ó jẹ́ ìyànu fún wọn, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì sí ilẹ̀kùn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí Olúwa wọn tí ó ti ṣubú, ó sì ti kú.
26 Nígbà tí wọ́n dúró tí wọn sì ń retí, Éhúdù ti sálọ. Ó ti gba ibi tí wọ́n ti ń gbẹ́ òkúta lére, ó sì sálọ sí Ṣéírà.
27 Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó fọn fèrè ní orí òkè Éfúráímù, fèrè ìpè ogun, ó sì kó ogun jọ lábẹ́ ara rẹ̀ bí olórí ogun.
28 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí Olúwa ti fi Móábù ọ̀ta yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jọ́dánì tí ó lọ sí ilẹ̀ Móábù, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá.
29 Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ará Móábù tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà.