Onídájọ́ 4:11-17 BMY

11 Ní àsìkò yìí Hébérì, ọ̀kan nínú ẹ̀yà Kẹ́nì, ti ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀yà Kénì, òun sì ń gbé ibòmíràn títí dé ibi igi óákù Ṣánanímù, tí ó wà ni agbégbé Kédésì (àwọn ẹ̀yà Kénì jẹ́ ìran Hóbábù ẹni tí i ṣe àna Móṣè).

12 Nígbà tí a sọ fún Ṣísérà pé Bárákì ọmọ Ábínóámù ti kó ogun jọ sí òkè Tábósì,

13 Ṣísérà kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun irin rẹ̀ tí ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀run (900) àti gbogbo àwọn ènìyàn (ọmọ ogun) tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Háróṣétì tí àwọn orílẹ̀ èdè wá sí ọ̀dọ̀ Kíṣónì.

14 Dèbórà sì wí fún Bárákì pé, “Lọ! Lónìí ni Olúwa fi Ṣísérà lé ọ lọ́wọ́, Olúwa ti lọ ṣíwájú rẹ.” Bárákì sì ṣíwájú, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì tẹ̀le e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tábórì.

15 Olúwa sì mú ìdàrúdàpọ̀ wá sí àárin ogun Sísérà, Olúwa sì fi ojú idà ṣẹ́gun Sísérà àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun àti ọmọ ogun orí ilẹ̀ ní iwájú Bárákì. Sísérà sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ó sì fi ẹṣẹ̀ sálọ.

16 Bárákì àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀ èdè, títí ó fi pa gbogbo àwọn ọmọ ogun Ṣísérà kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láàyè.

17 Ṣùgbọ́n Ṣísérà ti fi ẹṣẹ̀ sá lọ sí àgọ́ Jáélìa aya Hébérì ẹ̀yà Kénì: nítorí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àlàáfíà wà láàárin Jábínì ọba Háṣórì àti ìdílé Hébérì ti ẹ̀yà Kénì.