19 Sísérà wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ́ mí, jọ̀wọ́ fún mi ní omi mu.” Ó sì sí awọ wàrà kan, ó sì fún-un mu ó sì tún daṣọ bò ó padà.
20 Sísérà sọ fún Jáélì pé, “Kí ó dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, àti pé bí ẹnikẹ́ni bá béèrè bóyá òun wà níbẹ̀ kí ó sọ pé, ‘Kò sí ẹnìkankan ní ibẹ̀.’ ”
21 Ṣùgbọ́n Jáélì ìyàwó Hébérì mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó ṣùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin ó sì kú.
22 Nígbà tí Bárákì dé bí ó ti ń lépa Sísérà, Jáélì láti pàdé rẹ̀, wá, èmi yóò fi ẹni tí ìwọ ń wá hàn ọ́, báyìí ni ó tẹ̀lé e wọ inú àgọ́ lọ, kíyèsí Ṣísérà dùbúlẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú ìṣó àgọ́ ní agbárí rẹ̀ tí a ti kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin tí ó sì ti kú.
23 Ní ọjọ́ náà ni Ọlọ́run ṣẹ́gun Jábínì ọba àwọn ará Kénánì ní iwájú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
24 Ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì le, ó sì ń lágbára síwájú àti síwájú sí i lára Jábínì ọba Kénánì, títí wọ́n fi run òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.