Onídájọ́ 4:2-8 BMY

2 Nítorí náà Olúwa jẹ́kí Jábínì, ọba àwọn Kénánì, ẹni tí ó jọba ní Haṣórì, ṣẹ́gun wọn. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Ṣísérà ẹni tí ń gbé Hároṣeti-Hágóyímù.

3 Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Ísírẹ́lì lójú gidigidi fún ogún ọdún. Ísírẹ́lì ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́.

4 Dèbórà, wòlíì-obìnrin, aya Lápídótì ni olórí àti asíwájú àwọn ará Ísírẹ́lì ní àsìkò náà.

5 Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a ṣọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Dèbórà láàárin Rámà àti Bẹ́tẹ́lì ní ilẹ̀ òkè Éfúráímù, àwọn ará Ísírẹ́lì a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn Olúwa láti ẹnu rẹ̀.

6 Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Bárákì ọmọ Ábínóámù ẹni tí ń gbé ní Kádésì ní ilẹ̀ Náfítalì, ó sì wí fún-un pé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì pa á ní àṣẹ fún-un pé kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Náfítalì àti ẹ̀yà Ṣébúlúnì bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì ṣíwájú wọn lọ sí òkè Tábórì.

7 Èmi yóò sì fa Sísérà olórí ogun Jábínì, pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ àti àwọn ogun rẹ, sí odò Kíṣónì èmi yóò sì fi lé ọ lọ́wọ́ ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn níbẹ̀.

8 Bárákì sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.”