Onídájọ́ 4:6-12 BMY

6 Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Bárákì ọmọ Ábínóámù ẹni tí ń gbé ní Kádésì ní ilẹ̀ Náfítalì, ó sì wí fún-un pé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì pa á ní àṣẹ fún-un pé kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Náfítalì àti ẹ̀yà Ṣébúlúnì bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì ṣíwájú wọn lọ sí òkè Tábórì.

7 Èmi yóò sì fa Sísérà olórí ogun Jábínì, pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ àti àwọn ogun rẹ, sí odò Kíṣónì èmi yóò sì fi lé ọ lọ́wọ́ ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn níbẹ̀.

8 Bárákì sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.”

9 Dèbórà dá a lóhùn pé, “ó dára, èmi yóò bá ọ lọ ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí Olúwa yóò fi Sísérà lé obìnrin lọ́wọ́” Báyìí Dèbórà bá Bárákì lọ sí Kédésì.

10 Nígbà tí Bárákì pe ẹ̀yà ṣébúlúnì àti ẹ̀yà Náfítalì sí Kédésì ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Dèbórà pẹ̀lú bá wọn lọ.

11 Ní àsìkò yìí Hébérì, ọ̀kan nínú ẹ̀yà Kẹ́nì, ti ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀yà Kénì, òun sì ń gbé ibòmíràn títí dé ibi igi óákù Ṣánanímù, tí ó wà ni agbégbé Kédésì (àwọn ẹ̀yà Kénì jẹ́ ìran Hóbábù ẹni tí i ṣe àna Móṣè).

12 Nígbà tí a sọ fún Ṣísérà pé Bárákì ọmọ Ábínóámù ti kó ogun jọ sí òkè Tábósì,