2 “Nítorí bí àwọn olórí ti ṣíwájú ní Ísírẹ́lì,nítorí bi àwọn ènìyàn ti fi tọkàntọkàn wa,Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa!
3 “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọba! Ẹ̀yin ìjòyè!Èmi yóò kọrin nípa Olúwa, èmi yóò kọrinÈmi yóò kọrin sí Olúwa: Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
4 “Olúwa nígbà tí o jáde lọ láti Ṣéírì,nígbà tí o yan láti ilẹ̀ Édómù,ilẹ̀ mì tìtì, àwọn ọ̀run ya,ìkúùkù àwọ̀sámọ̀ da omi wọn sílẹ̀.
5 Àwọn òkè mì tìtì ní iwájú Olúwa Ísírẹ́lì ẹni tí ó ni Ṣínáì,níwájú Olúwa ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.
6 “Ní àwọn ọjọ́ Ṣámgárì ọmọ Ánátì,Ní àwọn ọjọ́ Jáélì, a kọ àwọn ojú ọ̀nà sílẹ̀;àwọn arìnrìnàjò ń gba kọ̀rọ̀ kọ́rọ́.
7 Àwọn akọni ìletò dínkù,wọ́n dínkù afi ìgbà tí Dèbórà dìde,ó dìde bí ìyá ní Ísírẹ́lì.
8 Nígbà tí Ísírẹ́lì bá yan Ọlọ́run àjèjì,ogun jíjà wọ ibodè ìlúa kò rí àpáta tàbí ọ̀kọ̀láàárin àwọn ẹgbàá ní Ísírẹ́lì