5 Àwọn òkè mì tìtì ní iwájú Olúwa Ísírẹ́lì ẹni tí ó ni Ṣínáì,níwájú Olúwa ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.
6 “Ní àwọn ọjọ́ Ṣámgárì ọmọ Ánátì,Ní àwọn ọjọ́ Jáélì, a kọ àwọn ojú ọ̀nà sílẹ̀;àwọn arìnrìnàjò ń gba kọ̀rọ̀ kọ́rọ́.
7 Àwọn akọni ìletò dínkù,wọ́n dínkù afi ìgbà tí Dèbórà dìde,ó dìde bí ìyá ní Ísírẹ́lì.
8 Nígbà tí Ísírẹ́lì bá yan Ọlọ́run àjèjì,ogun jíjà wọ ibodè ìlúa kò rí àpáta tàbí ọ̀kọ̀láàárin àwọn ẹgbàá ní Ísírẹ́lì
9 Inú mi yọ̀ sí àwọn aláṣẹ Ísírẹ́lìàwọn tí ó fi tínu tínu fi ara wọn rúbọẸ yín Olúwa!
10 “Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,ẹ̀yin tí ń jókòó láti se ìdájọ́,àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà,Ní ọ̀nà jìnjìn sí
11 ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi.Wọ́n ń sọ ti iṣẹ́ òdodo Olúwa níbẹ̀,àní iṣẹ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.“Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Olúwasọ̀ kalẹ̀ lọ sí ibodè.