12 “Àwọn igi sì tún sọ fún àjàrà pé, ‘Wá, kí o ṣe ọba wa.’
13 “Ṣùgbọ́n àjàrà dáhùn pé, ‘Ṣé kí èmi dẹ́kun àti máa so èṣo wáìnì mi èyí tí ó ń mú inú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn dùn láti máa ṣe olórí àwọn igi?’
14 “Ní ìparí gbogbo àwọn igi lọ bá igi ẹ̀gún wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Wá kí ó ṣe ọba wa.’
15 “Igi ẹ̀gún dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Bí lótítọ́ ni ẹ bá fẹ́ yàn mí ní ọba yín. Ẹ sá àṣálà sí abẹ́ ìbòji mi; ṣùgbọ́n tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ìná jáde láti inú igi ẹ̀gún kí ó sì jó àwọn igi Kédárì àti ti Lẹ́bánónì run!’
16 “Báyìí tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yín ṣe ohun tí ó ní ọlá àti pẹ̀lú ẹ̀mí òtítọ́ ní fífi Ábímélékì jọba, tí ó bá ṣe pé ohun tí ó tọ́ ni ẹ ṣe sí Jérú-Báálì àti ìdílé rẹ̀, bí ẹ bá san ẹ̀san tó yẹ fún un.
17 Nítorí pé baba mi jà nítorí yín, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu láti gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì;
18 ṣùgbọ́n lónìí ẹ̀yin ṣọ̀tẹ̀ sí ilé baba mi, ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ẹ ti pa àwọn àádọ́rin ọmọ rẹ̀, ẹ̀yin sì ti fi Ábímélékì ọmọ ẹrú-bìnrin rẹ̀ jọba lórí àwọn ènìyàn Ṣékémù nítorí tí ó jẹ́ arákùnrin yín.