1 Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ti dáwọ́lé títo àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì jọ lẹ́sẹẹsẹ, èyí tí ó ti múlẹ̀ ṣinṣin láàárin wa,
2 àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà tí ó ṣe ojú wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ ti fi lé wa lọ́wọ́.
3 Nítorí náà, ó sì yẹ fún èmi pẹ̀lú láti kọ̀wé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ bí mo ti wádìí ohun gbogbo fínnífínní láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, Tìófílù ọlọ́lá jùlọ,
4 kí ìwọ kí ó le mọ òtítọ́ ohun wọ̀n-ọn-nì tí a ti kọ́ ọ.
5 Nígbà ọjọ́ Hérọ́dù ọba Jùdéà, Àlùfáà kan wà, ní ipa ti Ábíà, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Sakaráyà: aya rẹ̀ sì ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìrin Árónì, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Èlísábẹ́tì.
6 Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn.
7 Ṣùgbọ́n wọn kò ní ọmọ, nítorí tí Èlísábẹ́tì yàgàn; àwọn méjèèjì sì di arúgbó.