38 “Màríà sì dáhùn wí pé, wò ó ọmọ-ọ̀dọ̀ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Ańgẹ́lì náà sì fi í sílẹ̀ lọ.
39 Ní ijọ́ wọ̀nyí ni Màríà sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Júdà;
40 Ó sì wọ ilé Sakaráyà lọ ó sì kí Èlísabẹ́tì.
41 Ó sì ṣe, nígbà tí Èlísábẹ́tì gbọ́ kíkí Màríà, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Èlísábẹ́tì sì kún fún Èmí mímọ́;
42 Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Alúbùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkúnfún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí.
43 Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá?
44 Sá wò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀.