6 Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn.
7 Ṣùgbọ́n wọn kò ní ọmọ, nítorí tí Èlísábẹ́tì yàgàn; àwọn méjèèjì sì di arúgbó.
8 Ó sì ṣe, nígbà tí ó ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà níwájú Ọlọ́run níipaṣẹ̀ tirẹ̀
9 Bí ìṣe àwọn àlùfáà, ipa tirẹ̀ ni láti máa fi tùràrí jóná, nígbà tí ó bá wọ inú tẹ́ḿpìlì Olúwa lọ.
10 Gbogbo Ìjọ àwọn ènìyàn sì ń gbàdúrà lóde ní àkókò sísun tùràrí.
11 Ańgẹ́lì Olúwa kan sì fi ara hàn án, ó dúró ní apá ọ̀tún pẹpẹ tùràrí.
12 Nígbà tí Sakaráyà sì rí i, orí rẹ̀ wúlé, ẹ̀rù sì bà á.