1 Ó sì ṣe, nígbà tí àìníye ìjọ ènìyàn péjọ pọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa sọ́ra yín nítorí ìwúkàrà àwọn Farisí tí í ṣe àgàbàgebè
2 Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn; tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀.
3 Nítorí náà ohunkóhun tí ẹ̀yin sọ ní òkùnkùn, ní gbangba ni a ó ti gbọ́ ọ; àti ohun tí ẹ̀yin bá sọ sí etí ní ìkọ̀kọ̀, lórí òrùlé ni a ó ti kéde rẹ̀.
4 “Èmi sì wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó ń pa ara ènìyàn kú, lẹ́yìn èyí, wọn kò sì ní èyí tí wọ́n lè ṣe mọ́.