18 Ó sì wí pé, “Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èṣo àti ọrọ̀ mi jọ sí.
19 Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, má a yọ̀.”
20 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, “Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó bèèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti tani nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?”
21 “Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó to ìsúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
22 sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Nítorí náà mo wí fún yín pé, ẹ má ṣe ṣàníyàn nítorí ọkàn yín pé, kínni ẹ̀yin ó fi bora.
23 Ọkàn sáà ju oúnjẹ lọ, ara sì ju aṣọ lọ.
24 Ẹ kíyèsí àwọn ẹyẹ ìwò: wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè: wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sáà ń bọ́ wọn: mélòómélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ!