24 Ẹ kíyèsí àwọn ẹyẹ ìwò: wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè: wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sáà ń bọ́ wọn: mélòómélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ!
25 Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ìgbé ayé rẹ̀?
26 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹyin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù?
27 “Ẹ kíyèsí àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Sólómọ́nì pàápàá lọ́sọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí.
28 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko ìgbẹ́ ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónì-ín, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la: mélòómélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin oní kékeré ìgbàgbọ́.
29 Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣàníyàn ọkàn.
30 Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀ èdè ayé lé kiri: Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ nǹkan wọ̀nyí.