26 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹyin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù?
27 “Ẹ kíyèsí àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Sólómọ́nì pàápàá lọ́sọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí.
28 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko ìgbẹ́ ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónì-ín, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la: mélòómélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin oní kékeré ìgbàgbọ́.
29 Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣàníyàn ọkàn.
30 Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀ èdè ayé lé kiri: Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ nǹkan wọ̀nyí.
31 Ṣùgbọ́n ẹ máa wá ìjọba Ọlọ́run, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.
32 “Má bẹ̀rù, agbo kékeré; nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fi ìjọba fún yín.