43 Ìbùkún ni fún ọmọ-ọ̀dọ̀ náà, nígbà tí olúwa rẹ̀ bá dé, tí yóò bá a kí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀.
44 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín yóò fi jẹ olórí ohun gbogbo tí ó ní.
45 Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá wí ní ọkàn rẹ̀, pé, ‘Olúwa mi fi ìgbà bíbọ̀ rẹ̀ falẹ̀!’ Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ìránṣẹ́-kùnrin àti ìráṣẹ́bìnrin tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àti sí mu àmupara:
46 Olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà yóò dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀, àti ní wákàtí tí kò dábàá, yóò sì jẹ ẹ́ níyà gidigidi, yóò sì yan ipò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.
47 “Àti ọmọọ̀dọ̀ náà, tí ó mọ ìfẹ́ olúwa rẹ̀, tí kò sì múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, òun ni a ó nà púpọ̀.
48 Ṣùgbọ́n èyí tí kò mọ̀, tí ó ṣe ohun tí ó yẹ sí lílù, òun ni a ó lù níwọ̀n. Nítorí ẹnikẹ́ni tí a fún ní púpọ̀, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a ó gbé bèèrè púpọ̀: lọ́dọ̀ ẹni tí a bá gbé fi púpọ̀ sí, lọ́dọ̀ rẹ ni a ó gbé bèèrè sí i.
49 “Iná ni èmi wá láti sọ sí ayé; kínni èmi sì ń fẹ́ bí kò ṣe kí a ti dá a ná!