51 Ẹ̀yin ṣe bí àlààáfíà ni èmi wá fi sáyé? Mo wí fún yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n bí kò ṣe ìyapa.
52 Nítorí láti ìsinsìn yìí lọ, ènìyàn márùn-ún yóò wà ní ilé kan náà tí a ó yà ní ipa, mẹ́ta sí méjì, àti méjì sí mẹ́ta.
53 A ó ya baba nípa sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọkùnrin sí baba; ìyá sí ọmọbìnrin, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, ìyá ọkọ sí ìyàwó ọmọ, àti ìyàwó ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀.”
54 Ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pẹ̀lú pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìkùukù àwọ̀sánmà tí ó ṣú ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, lọ́gán ni ẹ̀yin yóò sọ pé, ‘Ọ̀wàrà òjò ń bọ̀,’ a sì rí bẹ́ẹ̀.
55 Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúsù bá ń fẹ́, ẹ̀yin á ní, ‘Oòrùn yóò mú,’ yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀.
56 Ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin le mòye ojú ọ̀run àti ti ayé. Èé ha ti ṣe tí ẹ̀yin kò mọ àkókò yìí?
57 “Èé ha ti ṣe tí ẹ̀yin tìkárayín kò fi ro ohun tí ó tọ́?