6 Ológoṣẹ́ márùn ún sáà ni a ń tà lówó idẹ wẹ́wẹ́ méjì? A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run?
7 Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni a kà pé ṣánṣán. Nítorí náà kí ẹ má ṣe bẹ̀rù: ẹ̀yin ní iye lórí ju ológóṣẹ́ púpọ̀ lọ.
8 “Mo sì wí fún yín pẹ̀lú, Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú àwọn ènìyàn. Ọmọ ènìyàn yóò sì jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run:
9 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú ènìyàn, a ó sẹ́ ẹ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.
10 Àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ọmọ ènìyàn, a ó dárí rẹ̀ jìn-ín; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dárí rẹ̀ jìn-ín.
11 “Nígbà tí wọ́n bá sì mú yín wá sí sínágọ́gù, àti síwájú àwọn olórí, àti àwọn alásẹ, ẹ má ṣe ṣàníyàn pé, báwo tàbí ohun kínni ẹ̀yin yóò fèsì rẹ̀ tàbí kínni ẹ̀yin ó wí:
12 Nítorí Ẹ̀mí mímọ́ yóò kọ́ yín ní wákàtí kan náà ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ.”