26 “Nígbà náà ni ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Àwa ti jẹ, àwa sì ti mu níwájú rẹ, ìwọ sì kọ́ni ní ìgboro ìlú.’
27 “Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’
28 “Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpahínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Ábúráhámù, àti Ísáákì, àti Jákọ́bù, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde.
29 Wọn ó sì ti ilẹ̀ ìlà òòrùn, àti ìwọ̀-òòrùn wá, àti láti àríwá, àti gúsù wá, wọn ó sì jókòó ní ìjọba Ọlọ́run.
30 Sì wò ó, àwọn ẹni ẹ̀yìn ń bẹ tí yóò di ẹni iwájú, àwọn ẹni ìwájú ń bẹ tí yóò di ẹni ẹ̀yìn.”
31 Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhín-ín yìí: nítorí Hẹ́rọ́dù ń fẹ́ pa ọ́.”
32 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, ‘Kíyèsí i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lóní àti lọ́la, àti ní ijọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.’