12 Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, “Nígbà tí ìwọ bá se àṣè ọ̀sán má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà.
13 Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkù àrùn, àwọn amúkún-ún, àti àwọn afọ́jú:
14 Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítori wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ: ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòótọ́.”
15 Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jókòó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó wí fún Jésù pé, “Alábúkùn ni fún ẹni tí yóò jẹ oúnjẹ ase ní ìjọba Ọlọ́run!”
16 Jésù dá a lóhùn pé, “Ọkùnrin kan se àsè alẹ́ ńlá, ó sì pe ènìyàn púpọ̀.
17 Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Ẹ wá; nítorí ohun gbogbo ṣe tán!’
18 “Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ ní ohùn kan láti ṣe àwáwí. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’