29 Ó sì dáhùn ó wí fún bàbá rẹ̀ pé, ‘Wòó, láti ọdún mélòó wọ̀nyí ni èmi ti ń sìn ọ́, èmi kò sì rú òfin rẹ rí: ìwọ kò sì tí ì fi ọmọ ewúrẹ́ kan fún mi, láti fi bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe àríyá:
30 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tí ó fi panṣágà ru ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, ìwọ sì ti pa ẹgbọ̀rọ̀ màlúù àbọ́pa fún un.’
31 “Ó sì wí fún un pé, ‘Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ ń bẹ lọ́dọ̀ mi, ohun gbogbo tí mo sì ní, tìrẹ ni.
32 Ó yẹ kí a ṣe àríyá kí a sì yọ̀: nítorí àbúrò rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i.’ ”