1 Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú pé, “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ní ìríjú kan; òun náà ni wọ́n fi sùn ún pé, ó ti ń fi ohun-ìní rẹ̀ ṣòfò.
2 Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mọ́.’
3 “Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi: èmi kò lè walẹ̀; láti sàgbẹ̀ ojú ń tì mí.
4 Mo mọ èyí tí èmi yóò se, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi isẹ́ ìríjú, kí wọn kí ó le gbà mí sínú ilé wọn.’