10 “Ẹni tí ó bá ṣe olóòótọ́ ní ohun kínkinní, ó ṣe olóòótọ́ ní púpọ̀ pẹ̀lú: ẹni tí ó bá sì ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun kínkinní, ó ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun púpọ̀ pẹ̀lú.
11 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò bá ti jẹ́ olóòótọ́ ní mámónì àìṣòótọ́, tani yóò fi ọ̀rọ̀ tòótọ́ ṣú yín?
12 Bí ẹ̀yin kò bá sì ti jẹ́ olóòtítọ́ ní ohun tí í se ti ẹlòmíràn, tani yóò fún yín ní ohun tí í se ti ẹ̀yin tìkara yín?
13 “Kò sí ìránṣẹ́ kan tí ó le sin olúwa méjì: àyàfi kí ó kórìíra ọ̀kan, yóò sì fẹ́ èkejì; tàbí yóò fi ara mọ́ ọ̀kan yóò sì yan èkejì ní ìpọ̀sì. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run pẹ̀lú mámónì.”
14 Àwọn Farisí, tí wọ́n ní ojúkòkòrò sì gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì yọ sùtì sí i.
15 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni àwọn tí ń dáre fún ara yín níwájú ènìyàn; ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ ọkàn yín: nítorí èyí tí a gbé níyìn lọ́dọ̀ ènìyàn, ìríra ni níwájú Ọlọ́run.
16 “Òfin àti àwọn wòlíì ń bẹ títí di ìgbà Jòhánù: Láti ìgbà náà wá ni a ti ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, olúkúlùkù sì ń fi ipá wọ inú rẹ̀.