2 Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mọ́.’
3 “Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi: èmi kò lè walẹ̀; láti sàgbẹ̀ ojú ń tì mí.
4 Mo mọ èyí tí èmi yóò se, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi isẹ́ ìríjú, kí wọn kí ó le gbà mí sínú ilé wọn.’
5 “Ó sì pe àwọn ajigbèsè olúwa rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún èkínní pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ olúwa mi?’
6 “Ó sì wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún Òṣùwọ̀n òróró.’“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta.’
7 “Nígbà náà ni ó sì bi ẹnìkejì pé, ‘Èló ni ìwọ́ jẹ?’“Òun sì wí pé, ‘Ọgọ́rùnún òsùwọ̀n àlìkámà.’“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, kí o sì kọ ọgọ́rin.’
8 “Olúwa rẹ̀ sì yin aláìṣòótọ́ ìríjú náà, nítorí tí ó fi ọgbọ́n ṣe é: àwọn ọmọ ayé yìí sáà gbọ́n ní Ìran wọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ.