6 “Ó sì wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún Òṣùwọ̀n òróró.’“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta.’
7 “Nígbà náà ni ó sì bi ẹnìkejì pé, ‘Èló ni ìwọ́ jẹ?’“Òun sì wí pé, ‘Ọgọ́rùnún òsùwọ̀n àlìkámà.’“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, kí o sì kọ ọgọ́rin.’
8 “Olúwa rẹ̀ sì yin aláìṣòótọ́ ìríjú náà, nítorí tí ó fi ọgbọ́n ṣe é: àwọn ọmọ ayé yìí sáà gbọ́n ní Ìran wọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ.
9 Èmi sì wí fún yín, ẹ fi mámónì àìṣòótọ́ yan ọ̀rẹ́ fún ara yín pé, nígbà tí yóò bá yẹ, kí wọn kí ó le gbà yín sí ibùjókòó wọn títí ayé.
10 “Ẹni tí ó bá ṣe olóòótọ́ ní ohun kínkinní, ó ṣe olóòótọ́ ní púpọ̀ pẹ̀lú: ẹni tí ó bá sì ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun kínkinní, ó ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun púpọ̀ pẹ̀lú.
11 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò bá ti jẹ́ olóòótọ́ ní mámónì àìṣòótọ́, tani yóò fi ọ̀rọ̀ tòótọ́ ṣú yín?
12 Bí ẹ̀yin kò bá sì ti jẹ́ olóòtítọ́ ní ohun tí í se ti ẹlòmíràn, tani yóò fún yín ní ohun tí í se ti ẹ̀yin tìkara yín?