25 Ṣùgbọ́n kò lè sàìmá kọ́ jìyà ohun púpọ̀, kí a sì kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ ìran yìí.
26 “Bí ó ti rí ní ọjọ́ Nóà, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ ọmọ ènìyàn.
27 Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbéyàwó, wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí ó fi di ọjọ́ ti Nóà wọ inú ọkọ̀ lọ, kíkún omi sì dé, ó sì run gbogbo wọn.
28 “Bí ó sì ti rí ní ọjọ́ Lọ́ọ̀tì; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé;
29 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà tí Lọ́ọ̀tì jáde kúrò ní Ṣódómù, òjò iná àti súfúrù rọ̀ láti ọ̀run wá, ó sì run gbogbo wọn.
30 “Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ náà tí ọmọ ènìyàn yóò farahàn.
31 Ní ọjọ́ náà, ẹni tí ó bá wà lórí ilé, tí ẹrù rẹ̀ sì ń bẹ ní ilẹ̀, kí ó má se sọ̀kalẹ̀ láti wá kó o; ẹni tí ó bá sì wà ní oko, kí ó má ṣe padà sẹ́yìn.