37 Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹ́ḿpílì, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn-án àti lóru.
38 Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerúsálémù.
39 Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Gálílì, sí Násárẹ́tì ìlú wọn.
40 Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n: oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀.
41 Àwọn òbi rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerúsálémù ní ọdọọdún sí Àjọ-ìrékọjá.
42 Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí Jerúsálémù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà.
43 Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jésù dúró lẹ́yìn ní Jerúsálémù; Jóṣéfù àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀.