1 Ní ijọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹ́ḿpìlì tí ó sì ń wàásù ìyìn rere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn alàgbà dìde sí i.
2 Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe ǹkan wọ̀nyí? Tàbí tani ó fún ọ ní àṣẹ yìí?”
3 Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi pẹ̀lú yóò sì bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan; ẹ sì fi ìdáhùn fún mi.
4 Bamitísímù ti Jòhánù, láti ọ̀run wá ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?”
5 Wọ́n sì bá ara wọn gbérò pé, “Bí àwa bá wí pé, ‘Láti ọ̀run wá ni,’ òun ó wí pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’
6 Ṣùgbọ́n bí àwa bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ gbogbo ènìyàn ni yóò sọ wá ní òkúta, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé, wòlíì ni Jòhánù.”