29 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ.
30 Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ.
31 Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú.
32 Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú.
33 Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya tìtani yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sáà ni ín ní aya.”
34 Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún-ni.
35 Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún-ni.