34 Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún-ni.
35 Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún-ni.
36 Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn áńgẹ́lì dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde.
37 Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mósè tìkararẹ̀ sì ti fihàn ní ìgbẹ́, nígbà tí ó pe Olúwa ni Ọlọ́run Ábúráhámù, àti Ọlọ́run Ísáákì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù.
38 Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè: nítorí gbogbo wọn wà láàyè fún un.”
39 Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, “Olùkọ́ ìwọ wí rere!”
40 Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́.