20 “Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerúsálémù ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀.
21 Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdéà sá lọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrin rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbéríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá.
22 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ.
23 Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fí ọmú fún ọmọ mu ní ijọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí.
24 Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dì wọ́n ní ìgbékùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerúsálémù yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún.
25 “Àmì yóò sì wà ní ọ̀run, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpáyà híhó òkun àti ìgbì-omi.
26 Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì.