33 Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.
34 “Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn.
35 Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé.
36 Ǹjẹ́ kì ẹ máa sọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ baà lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.”
37 Lọ́sàn-án, a sì máa kọ́ni ní tẹ́ḿpílì: lóru, a sì máa jáde lọ wọ̀ lórí òkè tí à ń pè ní òkè Ólífì.
38 Gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá ní tẹ́ḿpílì ní kùtùkùtù òwúrọ̀, láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.