44 Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀.
45 Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá ó bá wọn, wọ́n ń sùn fún ìbànújẹ́.
46 Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹ́wò.”
47 Bí ó sì ti ń sọ lọ́wọ́, kíyèsí i, ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti ẹni tí a ń pè ní Júdásì, ìkan nínú àwọn méjìlá, ó ṣáájú wọn, ó súnmọ́ Jésù láti fi ẹnu kò ó ní ẹnu.
48 Jesù sì wí fún un pé, “Júdásì, ìwọ yóò ha fi ìfẹnukonu fi Ọmọ ènìyàn hàn?”
49 Nígbà tí àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ń wo bí nǹkan yóò ti jásí, wọ́n bi í pé, “Olúwa kí àwá fi idà ṣá wọn?”
50 Ọ̀kan nínú wọn sì fi idà ṣá ọmọ-ẹ̀yìn olórí àlùfáà, ó sì gé etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù.