3 Pílátù sì bi í léèrè, wí pé, “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù?”Ó sì dá a lóhùn wí pé, “Ìwọ wí i.”
4 Pílátù sì wí fún àwọn Olórí àlùfáà àti fún ìjọ ènìyàn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ Ọkùnrin yìí.”
5 Wọ́n sì túbọ̀ tẹnumọ́ ọn pé, “Ó ń ru ènìyàn sókè, ó ń kọ́ni káàkiri gbogbo Jùdéà, ó bẹ̀rẹ̀ láti Gálílì títí ó fi dé ìhínyìí!”
6 Nígbà tí Pílátù gbọ́ orúkọ Gálílì, ó béèrè bí ọkùnrin náà bá jẹ́ ará Gálílì.
7 Nígbà tí ó sì mọ̀ pé ará ilẹ̀ Hẹ́rọ́dù ni, ó rán an sí Hẹ́rọ́dù, ẹni tí òun tìkárarẹ̀ wà ní Jerúsálémù ní àkókò náà.
8 Nígbà tí Hẹ́rọ́dù, sì rí Jésù, ó yọ̀ gidigidi; nítorí tí ó ti ń fẹ́ rí i pẹ ó sáà ti ń gbọ́ ìhìn púpọ̀ nítorí rẹ̀; ó sì ń retí láti rí i kí iṣẹ́ àmì díẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe.
9 Ó sì béèrè ọ̀rọ̀ púpọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀; ṣùgbọ́n kò da a lóhùn rárá.