42 Ó sì wí pé, “Jésù, rántí mi nígbà tí ìwọ́ bá dé ìjọba rẹ.”
43 Jésù sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónì-ín ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Párádísè!”
44 Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsànán ọjọ́.
45 Òòrùn sì ṣóòkùn, aṣọ ìkéle ti tẹ́ḿpílì sì ya ní àárin méjì,
46 Nígbà tí Jésù sì kígbe lóhùn rara, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé!” Nígbà tí ó sì wí èyí tan, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.
47 Nígbà tí balógun ọ̀rún rí ohun tí ó ṣe, ó yin Ọlọ́run lógo, wí pé, “Dájúdájú olódodo ni ọkùnrin yìí!”
48 Gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ láti rí ìran yìí, nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọ́n lu ara wọn ní oókan àyà, wọ́n sì padà sí ilé.