46 Nígbà tí Jésù sì kígbe lóhùn rara, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé!” Nígbà tí ó sì wí èyí tan, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.
47 Nígbà tí balógun ọ̀rún rí ohun tí ó ṣe, ó yin Ọlọ́run lógo, wí pé, “Dájúdájú olódodo ni ọkùnrin yìí!”
48 Gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ láti rí ìran yìí, nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọ́n lu ara wọn ní oókan àyà, wọ́n sì padà sí ilé.
49 Àti gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀, àti àwọn obìnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Gálílì wá, wọ́n dúró lókèrè, wọ́n ń wo nǹkan wọ̀nyí.
50 Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jóṣẹ́fù, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatíyà. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòótọ́.
51 Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn; òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run.
52 Ọkùnrin yìí tọ Pílátù lọ, ó sì tọrọ òkú Jésù.