9 Wọ́n sì padà ti ibojì wá, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá, àti fún gbogbo àwọn ìyókù.
10 Màríà Magaléènì, àti Jóánnà, àti Màríà ìyá Jákọ́bù, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn sì ni àwọn tí ó ròyìn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn àpósítélì.
11 Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì dàbí ìsọkúsọ lójú wọn, wọn kò sì gbà wọ́n gbọ́.
12 Nígbà náà ni Pétérù dìde, ó súré lọ sí ibojì; nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnrarawọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe.
13 Sì kíyèsí i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ijọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Èmáúsì, tí ó jìnnà sí Jerúsálémù níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀.
14 Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀.
15 Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jésù tìkara rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ.